06/02/2018
AWON MERIN TO WA ILE AIYE
Gbogbo eda lo ni ipa kan tabi meji lati ko ninu aiye yi. Awon kan si wa ti won ri ile aiye yi wa, koo da won o kabamo pe won wa si ile aiye. Awon kan si wa to je wipe bi a ba tun tun ile aiye da, won o ni wa si ibe mo.
Awon merin kan pataki kan wa ti won wa ile aiye yi.
1. Awon ti won wa se tabi ri ile aiye
2. Awon ti won sin eniyan wa aiye.
3. Awon ti won wa woran ohunti awon kan wa se ninu aiye
4. Awon ti won wa da ile aiye ru.
1. Awon ti won wa se ile aiye je awon kan pataki ti Olorun diidii da lati wa ko ipa to joju laiye. Irufe awon be je awon eniyan manigbagbe yala ninu ebi, laarin ilu, lorile ede ati lawujo. Opolopo ma nbola fun iru awon eniyan yi, bee si ni ase won ma mule daindain. Bi Olorun se ni agbara too, ko wa si idile kan tabi ebi kan ti irufe awon eniyan yi kii wa, yala o le je akobi tabi abigbeyin. Awon irufe eniyan be maa saba ni awon ilakoja to lagbara tabi isoro, sugbon abuda won a ma mu won de ipo nla naa. Won je oloriire eniyan, awon eda yio ku si ma fe ki afi iru awon eniyan yi se olori won. Won je oni ola ati eni eye. Bi iru awon eniyan ba wa ninu ile iwe, oun ni yi ma ko ipa tojoju. Bi o si ko ise ni, yio saa je eniyan oto larin awon yio ku. Ki wo enikan se ile aiye re, bee sini gbogbo bi yio se ma tesiwaju ni yio ma wa ninu ero okan re nigbogbo igba. Ki gbo ohun tabi ariwo oja, o ma saba ro ojo ola daadaa. Bi se wa wu ki o le tabi ki ogun naa poto, yio saa de ipo nla naa.
2. Awon ti won sin eniyan wa aiye je irufe awon ti won o le da nkankan se lai si atilehin awon kan. Won ko le da ronu, won ko si le gbe igbese kan ayafi ti won ba ti won lati se. Won ki ronu ojo ola, sugbon ohun ti won je lowo nikan niwon mo, ko si ironu fun ojo ola. Gbogbo ilakaka won ni ki won sati jagba nibi jagba lohun. Awon eniyan ma satileyin fun awon ti won ri ile aiye wa, a si ma saba lowon fun aseyori awon eniyan nla.
3. Awon ti won wa woran ohunti awon kan wa se ninu aiye je awon ti won o ni ire kan lati se, won je agba ofifo, ejo ti o koja lori apata ti ko ni ipa kan. Irufe awon eniyan yi ma ya ole(Lazy) ti won kiife lati se nkankan. Won o si yato si awon ti won si eniyan wa aiye. Iru awon eniyan yi saba ma wa ni ipo eyin. Bi won kawe tabi ko ise won o ni ni suru lati se aseyori ise tabi iwa naa.
4. Awon ti won wa da ile aiye ru je awon eniyan buruku laarin awujo. Gbogbo ohun rere ti awon ti won ri ile aiye wa ni irufe awon eniyan yi fe lati baje. Awon eniyan yi ki si lawujo bi nkan yio se tesiwaju aya fi ki nkan baje. Aki saba fe iru won ku lawujo nitori wipe tibi tire lada ile aiye. Gbogbo ila kaka won ni ki nkan sati daru nitori won mo wipe bi nkan bati daru tan won a ri je ni be. Ti won ba wa ninu ebi, ebi o ni ifokan bale nitori wipe ohun ni yi da ebi na ru. Bi won si wa ni ile se, bi yio se ma fi ori enikan gba ikeji ni yio ma se. Bi a ba won wo oko papo, ija ni saa. Bi eniyan si fe iru won ni iyawo taki oko, ituka ni yio gbeyin igbeyawo be. Gbogbo ala ati iran won ijamba ni. Gbogbo ibi ti e ba ti ri won, won a saa dawon mo saa ni, nitori iwa owo won.
Nitori na ore e wo lo wa ninu irufe Awon Eniyan merin yii?